Jump to content

James Weldon Johnson

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
James Weldon Johnson

James Weldon Johnson tí a bí ní ọjọ́ kẹtadinlogun oṣù kẹfà ọdún 1871, tí ó sì kú ní ọjọ́ kẹrìndílógbọ̀n, oṣù kẹfà ọdún 1938 jẹ́ òǹkọ̀wé àti ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkàa.Ó sì fẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́mọnìyàn bíi rẹ̀ Grace Nail Johnson. Johnson jẹ́ olórí àwọn ẹgbẹ́ kan tíí rísí ìgbèrú àwọn èèyàn aláwọ̀kan (NAACP), ní bí tí oti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní ọdún 1917. Ní ọdún 1920, Òun ni ará Amẹ́ríkà aláwọ̀ dúdú àkọ́kọ́ tó jẹ́ Awé fún ẹgbẹ́ náà. Ó wà ní ipò yìí láàrin ọdún 1920 sí 1930. Johnson gbèrú níbi akitiyàn rẹ̀ gẹ́gẹ́bí òǹkọ̀wé, ó sì gbajúmọ̀ ní gbà Harlem Renaissance fún àwọn ewì, ìtàn àròsọ àti ìwé àkójọpọ̀ àwọn ìtàn ìbílẹ̀ tí ó kọ. Ó kọ ẹsẹ orin fún àwọn "Lift Every Voice and Sing", tí ó padà di orin orilẹ-èdè fún àwọn ẹ̀yà Negro.